Genesis 19:24-28

24 aNígbà náà ni Olúwa rọ̀jò iná àti Sulfuru (òkúta iná) sórí Sodomu àti Gomorra—láti ọ̀run lọ́dọ̀ Olúwa wá. 25Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀. 26 bṢùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀.

27Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Abrahamu sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa. 28 cÓ sì wo ìhà Sodomu àti Gomorra àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru.

Copyright information for YorBMYO